Ojú ìwòye Bíbélì nípa ohun ìní
Ojú ìwòye Olúwa nípa ọrọ̀
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. (Ìfihàn 2:9)
Ojú ìwòye ènìyàn nípa ohun ìní
Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó, àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì. (Jobu 5:5)
Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò lè dúró pẹ́; bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀. (Jobu 15:29)
Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà. (Jobu 20:10)
Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá. (Jobu 20:15)
Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀. Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n; nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́. “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀. (Jobu 20:18-20)
...òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀. Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run. (Jobu 20:26)
Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run. (Jobu 20:28)
Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà. (Jobu 21:13)
Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré. (Jobu 21:16)
Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró. Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ, tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀, lórí erùpẹ̀ àti wúrà Ofiri lábẹ́ òkúta odò, nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. (Jobu 22:23-25)
“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè. (Jobu 27:13)
Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀; àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó; àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀. (Jobu 27:16-17)
Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín, wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn, àti ọdún wọn nínú afẹ́. (Jobu 36:11)
Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí? Tàbí ipa agbára rẹ? (Jobu 36:19)
Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní. Ọgbọ́n jẹ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní. (Oniwaasu 7:11-12)
A kì í mú nǹkan kan lọ nígbà tí a bá kú
Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀. Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú, ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú. Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀. Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere. Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀ àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé. Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé. (Saamu 49:16-20)
Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan. Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere, nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un. Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀, bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀. (Oniwaasu 5:13-15)
Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. (1 Timotiu 6:7)
“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ. (Saamu 39:6)
O kò lè ra ìràpadà ọkàn rẹ
Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé? Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká, àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn. Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run. Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀, (Saamu 49:5-8)
Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú, ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. (Òwe 11:4)
Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀? (Matiu 16:26)
Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? (Marku 8:36-37)
Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. (Luku 9:25)
Ọrọ̀ ń mú “ọ̀rẹ́” púpọ̀ wá
Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀. (Òwe 14:20)
Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Òwe 19:4)
Ọrọ̀ kì í pẹ́
Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí? Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run. (Òwe 23:4-5)
Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ, nítorí tí ó ń wo èrè náà. (Heberu 11:24-26)
Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. (1 Peteru 1:7)
Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. (1 Peteru 1:18)
Gbogbo ohun ìní kò jámọ́ nǹkan bí a bá fi wé mímọ Jesu
Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi, (Filipi 3:7-8)
Ọrọ̀ kò dánilójú
Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; (1 Timotiu 6:17)
Ọrọ̀ kò wúlò láìsí Olúwa
Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi. Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní: gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn; ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni. (Oniwaasu 2:4-11)
Ohun tí ó níye lórí ju ọrọ̀ lọ
A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀. A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta safire díye lé e. Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ. Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀. (Jobu 28:15-19)
Ohun díẹ̀ tí olódodo ní, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú; (Saamu 37:16)
Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ, bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá. (Saamu 119:14)
Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ. (Saamu 119:72)
Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ, (Saamu 119:127)
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i, nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́. Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá. (Òwe 3:13-16)
Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn, nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e. (Òwe 8:10-11)
Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà, ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́, mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún. (Òwe 8:18-21)
Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu. (Òwe 15:16)
Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ. (Òwe 16:8)
Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà! (Òwe 16:16)
Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga. (Òwe 16:19)
Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà. (Òwe 19:1)
Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ, ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye. (Òwe 20:15)
Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ. (Òwe 22:1)
Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla. (Òwe 28:6)
Ẹni tí a fún ní púpọ̀, púpọ̀ ni a ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀
Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i. (Luku 12:48)
Ìbùkún ọrọ̀
A ó fi aásìkí san èrè fún olódodo
Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo. (Òwe 13:21)
Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn. (Òwe 15:6)
Ọrọ̀ fún ẹni tí ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn. Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru. Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere. (Saamu 1:1-3)
Àwọn tí ó ní aásìkí yóò sin Olúwa
Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn; gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè. (Saamu 22:29)
Gbígbàdúrà fún aásìkí
...kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn, kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo. (Saamu 106:5)
Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu; àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere. Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀, àti ìre nínú ààfin rẹ̀. (Saamu 122:6-7)
Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo. (Saamu 128:5)
Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ. (3 Johanu 2)
Àwọn ọlọ́rọ̀ olùfọkànsìn
Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀. (Gẹnẹsisi 12:5)
Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà. (Gẹnẹsisi 13:2)
Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. (Gẹnẹsisi 15:13-14)
Abrahamu sì ti di arúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún un ni gbogbo ọ̀nà, (Gẹnẹsisi 24:1)
Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúńdíá ni, kò sì tí ì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi. (Gẹnẹsisi 24:16)
Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin àti ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. (Gẹnẹsisi 24:35)
Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún ọdún ni ọdún kan náà, nítorí Olúwa bùkún un. Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀. (Gẹnẹsisi 26:12-14)
Nítorí ìdí èyí, Jakọbu di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin, ìránṣẹ́bìnrin pẹ̀lú ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. (Gẹnẹsisi 30:43)
Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á. (Gẹnẹsisi 33:11)
Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn. (Gẹnẹsisi 41:42)
Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.” (Gẹnẹsisi 45:13)
Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti. (Gẹnẹsisi 46:6)
Àwọn ará Israẹli sì tẹ̀dó sí Ejibiti ní agbègbè Goṣeni. Wọ́n ní ohun ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye. (Gẹnẹsisi 47:27)
Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógun tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.” (Joṣua 22:8)
Naomi ní ìbátan kan láti ìdílé Elimeleki ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi. (Rutu 2:1)
“Ẹ̀yin ọmọbìnrin Israẹli, ẹ sọkún lórí Saulu, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fi wúrà sí ara aṣọ yín. (2 Samuẹli 1:24)
Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsi i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́. (1 Ọba 10:4, 7)
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ. Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. (1 Ọba 3:11-13)
Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò baba a rẹ̀ Dafidi. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Israẹli sì gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. (1 Kronika 29:23)
Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀. Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. (1 Kronika 29:28)
Ọlọ́run wí fún Solomoni pé, “Níwọ́n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí. Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.” (2 Kronika 1:11-12)
Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ. (2 Kronika 9:22)
Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀. (2 Kronika 17:5)
Lára àwọn ará Filistini, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jehoṣafati, àwọn ará Arabia sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún un, ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) àgbò àti ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) òbúkọ. Jehoṣafati sì ń di alágbára nínú agbára sí i, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìṣúra púpọ̀ ní Juda (2 Kronika 17:11-12)
Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀. (2 Kronika 18:1)
Hesekiah ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye. Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí tuntun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àṣémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran. Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Ọlọ́run ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá. Hesekiah ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gihoni. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dafidi. Ó ṣe àṣeyọrí rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. (2 Kronika 32:27-30)
Wọ́n gba àwọn ìlú olódi àti ilẹ̀ ọlọ́ràá; wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kànga tí a ti gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà, àwọn ọgbà olifi àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáradára; wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ. (Nehemiah 9:25)
Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ. (Jobu 1:3)
Nígbà náà ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ga ní gbogbo agbègbè ìjọba Babeli. (Daniẹli 3:30)
Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, (Matiu 27:57)
Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan. Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i. (1 Kọrinti 4:8, 11-12)
Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà, ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín. Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀, mo sì tún ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. (Filipi 4:11-18)
Inú Olúwa dùn sí aásìkí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀
Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú; kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa, sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.” (Saamu 35:27)
Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò ní aásìkí
Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú. A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn, wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró; àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún. Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀. Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́rìí rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà, nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí ó dára jù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé. (Heberu 11:36-40)
Jesu yẹ láti gba ọrọ̀
Wọn ń wí lóhùn rara pé: “Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa, láti gba agbára, àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá, àti ògo, àti ìbùkún.” (Ìfihàn 5:12)
Àwọn ọlọ́gbọ́n lè di ọlọ́rọ̀
Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá. (Òwe 14:24)
Bí a ṣe ń ní ọrọ̀
Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀; nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n. (Òwe 24:3-4)
Ohun tí ń dí ènìyàn lọ́wọ́ láti ní ọrọ̀
Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà: ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀. (Òwe 21:17)
Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn. (Òwe 22:16)
Ewu ọrọ̀
Ìfẹ́ ọrọ̀
Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn. (Saamu 62:10)
Ìgbéraga
Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ. (Esekiẹli 28:4-5)
Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; (1 Timotiu 6:17)
Àwọn ọlọ́rọ̀ kò gbọdọ̀ gbéraga nítorí ayé kúrú
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga. Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ. Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀. (Jakọbu 1:9-11)
Ṣògo nínú Olúwa, kì í ṣe nínú ọrọ̀
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé: òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́, ìdájọ́ àti òdodo ní ayé, nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” Olúwa wí. (Jeremiah 9:23-24)
Ọrọ̀ ń fúnni ní ìmọ̀lára ààbò
Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní. (Òwe 10:15)
Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn; wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni. (Òwe 18:11)
Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé, “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.” Nípa ojúrere rẹ, Olúwa, ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára; ìwọ pa ojú rẹ mọ́, àyà sì fò mí. (Saamu 30:6-7)
Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀
Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé, ibùgbé wọn láti ìrandíran, wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé. (Saamu 49:10-12)
Ọrọ̀ máa ń ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀
Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà. Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.” Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.) Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. (Gẹnẹsisi 13:5-11)
Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún ọdún ni ọdún kan náà, nítorí Olúwa bùkún un. Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀. Nítorí náà àwọn ará Filistini ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́. Nígbà náà ni Abimeleki wí fún Isaaki pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.” (Gẹnẹsisi 26:12-16)
Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà. Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn. (Gẹnẹsisi 36:6-7)
Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀. (Isaiah 5:8)
Ọrọ̀ lè ya àwọn Kristẹni sọ́tọ̀
Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan. Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere. Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín. (1 Kọrinti 11:18-22)
Ọrọ̀ jẹ́ ẹlẹ́tàn/ó lè fún èso pa
Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú. (Òwe 11:18)
Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa. Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀. (Matiu 13:4-5, 7, 22)
Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. (Marku 4:2-3, 7, 18-19)
Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún; ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa. Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó. (Luku 8:7, 14)
Ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba náà
Ẹnìkan sì wá ó bí Jesu pé, “Olùkọ́, ohun rere kí ni èmi yóò ṣe, kí èmi kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?” Jesu dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.” Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ” Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?” Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?” Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.” (Matiu 19:16-26)
Bí Jesu ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Jesu béèrè pé, arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere. Ìwọ mọ àwọn òfin bí: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ purọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ” Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.” Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!” Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.” Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?” Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.” (Marku 10:17-27)
Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Luku 18:28-30)
Àwọn ọlọ́rọ̀ tí kò mọ Olúwa yóò yà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí láé
“Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́. Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju, Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun, àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín; Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’ “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró. (Luku 16:19-25)
Àwọn ọlọ́rọ̀ rò pé àwọn gbọ́n
Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀. (Òwe 28:11)
Bí àwọn ọlọ́rọ̀ ṣe ń ṣe sí àwọn tálákà
Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra. (Òwe 18:23)
Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè. (Òwe 22:7)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí? (Jakọbu 2:6-7)
Ọrọ̀ lè mú kí a gbàgbé Olúwa
Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú yín dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín, fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu láti fi fún un yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńlá ńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ, àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kànga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n. Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú. (Deuteronomi 6:10-12)
Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá. Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú. Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta. Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín. Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.” Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí. (Deuteronomi 8:9-18)
Nígbà tí mo ti mú wọn wá sí ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin, ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí ní ìbúra fún àwọn baba ńlá wọn, àti nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí ó sì tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì gbilẹ̀, wọn yóò yí padà sí ọlọ́run mìíràn wọn yóò sì sìn wọ́n, wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀, wọn yóò sì da májẹ̀mú mi. (Deuteronomi 31:20)
“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú. Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan. Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’ Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi. (Òwe 30:7-9)
Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu, ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’ Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́. Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn, nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́ nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ. (Jeremiah 22:21-22)
Nítorí tí ìwọ wí pé, èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran. (Ìfihàn 3:17-18)
Ọrọ̀ ń dá ìlara sílẹ̀
Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún ọdún ni ọdún kan náà, nítorí Olúwa bùkún un. Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀. (Gẹnẹsisi 26:12-14)
Nígbà náà ni Abimeleki wí fún Isaaki pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.” (Gẹnẹsisi 26:16)
Jakọbu sì gbọ́ pé àwọn ọmọ Labani ń wí pé, “Jakọbu ti gba gbogbo ohun ìní baba wa, ó sì ti kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀ lára àwọn ohun tí í ṣe ti baba wa.” (Gẹnẹsisi 31:1)
Ègún ọrọ̀
Ègún jíjí gbé
Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà. (Òwe 13:8)
Ègún àìrí oorun sùn
Oorun alágbàṣe a máa dùn, yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn rárá. (Oniwaasu 5:12)
Ègbé tí a kéde sórí àwọn ọlọ́rọ̀
“Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín. (Luku 6:24)
Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn. Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa. (Jakọbu 5:1-5)
Èéṣe tí àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe rere?
Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa. Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀. Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo; òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i; òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Saamu 10:3-5)
Ti Dafidi. Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko, wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù. Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ. Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà. Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀; nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. (Saamu 37:1-2, 7, 9-11)
Saamu ti Asafu. Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli, fún àwọn ọlọ́kàn funfun. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán. Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú. Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára. Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn. Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ. Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n. Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga. Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run ahọ́n wọn gba ipò ayé. Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀? Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?” Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí, ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀. Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀. Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀. Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi, títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi. Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun. Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá! Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn. (Saamu 73:1-20)
Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan. (Òwe 11:16)
Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkígbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn? Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀, wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso. Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn, o jìnnà sí ọkàn wọn. (Jeremiah 12:1-2)
Àwọn ọlọ́rọ̀ aláìmọ Ọlọ́run
Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli. (1 Samuẹli 25:2)
Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko. (Esteri 1:4)
Hamani gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọlá fún un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tókù lọ. (Esteri 5:11)
Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin. (Isaiah 2:7)
Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀. (Esekiẹli 27:33)
“Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki. (Daniẹli 11:2)
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀. (Luku 19:2)
Àṣẹ pé kí a má ṣe wá aásìkí àwọn ènìyàn kan
Ìwọ kò gbọdọ̀ wá àlàáfíà, tàbí ire wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láààyè. (Deuteronomi 23:6)
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’ (Esra 9:12)
Ọ̀nà tí kò tọ́ láti ní aásìkí
Àwọn kan ń ní aásìkí nípa dídẹ́ṣẹ̀ láìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn
Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.” (Hosea 12:8)
Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn. (Sekariah 11:5)
Àwọn kan ń ṣe bí ẹlẹ́sìn kí wọ́n lè ní aásìkí
Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.” (Onidajọ 17:13)
Oríṣiríṣi
...bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́. (Òwe 2:4)
Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ, tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ, nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn. (Oniwaasu 10:20)
Nígbà mìíràn àwọn ènìyàn ń parọ́ nípa ipò owó wọn
Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀. (Òwe 13:7)
A fi owó ṣàpèjúwe iye Ìjọba Ọlọ́run
“Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà. “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á. (Matiu 13:44-46)
A fi ìgbésí ayé òdodo wé fàdákà
Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà, ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí. (Òwe 10:20)
Ìdájọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ tí kò mọ Ọlọ́run
Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari. (Isaiah 15:7)
Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò! (Jeremiah 51:13)
Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ìwọ Tire wí pé, “Ẹwà mi pé.” “ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀. “ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ. “ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ. “ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ. “ ‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ. “ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ. “ ‘Damasku ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari, àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ. “ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn. “ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ. “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà. “ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ. Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ. “ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò ní ọjà rẹ a ti mú ọ gbilẹ̀ a sì ti ṣe ọ́ lógo ní àárín gbùngbùn Òkun. Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ wá sínú omi ńlá. Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ ní àárín gbùngbùn Òkun. Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ, àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ. Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ, àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ tí ó wà ní àárín rẹ yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun ní ọjọ́ ìparun rẹ. (Esekiẹli 27:3, 12-27)
Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀ ó ń so èso fún ara rẹ̀. Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀. Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run. (Hosea 10:1-2)
Ẹ hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà, gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò, gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun. Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun, àti ilé wọn yóò sì run. Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí wáìnì láti inú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.” Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé. (Sefaniah 1:11, 13, 18)
Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí eruku, àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro. Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun, a ó sì fi iná jó o run. (Sekariah 9:3-4)
Ọba kò gbọdọ̀ lọ́rọ̀ jù
Síwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Ejibiti láti wá àwọn ẹṣin sí i, nítorí pé Olúwa ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.” Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. (Deuteronomi 17:16-17)
Àwọn ọba ṣàìgbọràn sí àṣẹ pé kí wọ́n má lọ́rọ̀ jù
Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé ẹṣin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin. (1 Ọba 4:26)
Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì wúrà, láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Arabia, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀. Solomoni ọba sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan. Ó sì túnṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) asà wúrà lílù, pẹ̀lú òsùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí asà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lebanoni. Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ eyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó. Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni ìrọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí. Gbogbo ohun èlò mímu Solomoni ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lebanoni sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí nǹkan kan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. Ọba sì ní ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hiramu ní Òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tarṣiṣi ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá. Solomoni ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ. Gbogbo ayé sì ń wá ojú Solomoni láti gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sí i ní ọkàn. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún olúkúlùkù àwọn tí ń wá sì ń mú ẹ̀bùn tirẹ̀ wá, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò wúrà àti ẹ̀wù, àti tùràrí olóòórùn dídùn, ẹṣin àti ìbáaka. Solomoni sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ; ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú ọba ní Jerusalẹmu. Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti igi kedari ni ó ṣe kí ó dàbí igi sikamore tí ń bẹ ní àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. A mú àwọn ẹṣin wá fún Solomoni láti Ejibiti àti láti Kue, oníṣòwò ọba rà wọ́n láti Kue fún owó. (1 Ọba 10:14-28)
Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu. Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè. Àwọn ẹṣin Solomoni ní a gbà láti ìlú òkèrè Ejibiti àti láti kún ọ̀gbọ̀ oníṣòwò ti ọba ni gba okun náà ní iye kan. Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Ejibiti. Fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin méjìdínláàádọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hiti àti ti àwọn ará Aramu. (2 Kronika 1:14-17)
Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.” Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni. Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá. Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda. Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀. Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì, láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni. Ọba Solomoni sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà sí ọ̀kánkán asà. Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì wúrà nínú àpáta kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ààfin ti ó wà ní igbó Lebanoni. Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú eyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó. Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpótí ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhà méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìgbọ́wọ́lé, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn. Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn. Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Hiramu ń bojútó. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin àti ìnàkí. Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ. Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀. Ní ọdọọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹṣin àti ìbáaka wá. Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu. Ó sì jẹ ọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò Eufurate títí dé ilé àwọn ará Filistini àti títí ó fi dé agbègbè ti Ejibiti. Ọba sì sọ fàdákà dàbí òkúta ní Jerusalẹmu, àti igi kedari ni ó sì ṣe bí igi sikamore, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. (2 Kronika 9:8-27)
Àsọtẹ́lẹ̀
Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀. (Saamu 45:12)
Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n. Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?” Hesekiah si dáhùn pe, “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi. Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.” Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí. (Isaiah 39:2, 4-6)
Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá. Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani. Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá, wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa. Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí; ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn, pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn, fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́. Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀, a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun. (Isaiah 60:5-6, 9, 11)
A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo. Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn. (Isaiah 61:6-7)
Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. (Hagai 2:7)
“Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ” (Sekariah 1:17)
Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ” (Sekariah 7:7)
Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà. (Ìfihàn 6:15-16)
Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn; àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní àmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí àmì orúkọ rẹ̀. (Ìfihàn 13:16-17)
A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀; (Ìfihàn 17:4)
Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú. Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.” (Ìfihàn 18:3)
“Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́. Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti perli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu. Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn. “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé. Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali! Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’ “Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré, wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’ (Ìfihàn 18:11-19)
A lo ìrètí ọrọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwúrí
Ẹ lè máa gbé láàrín wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrín wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.” Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà. Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san án, kí ẹ sá à jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.” (Gẹnẹsisi 34:10-12)
Wí pé, “Ìwà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárín wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gba ààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ́n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú. Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárín wa.” (Gẹnẹsisi 34:21, 23)
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli wí pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò rí i bí ọkùnrin yìí ṣe ń jáde wá? Ó jáde wá láti pe Israẹli níjà. Ọba yóò fún ọkùnrin tí ó bá pa á ní ọrọ̀ púpọ̀. Yóò tún fi ọmọ rẹ̀ obìnrin fún un ní ìyàwó, yóò sì sọ ilé e baba rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú sísan owó orí ní Israẹli.” (1 Samuẹli 17:25)