Ìdánwò fífúnni
Ìdánwò ìgbàgbọ́
Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí? Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀. (Jakọbu 2:14-17)
Ìdánwò bóyá ìfẹ́ Ọlọ́run ń gbé inú wa
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? (1 Johanu 3:17)
Ìdánwò ìfẹ́ sí aládùúgbò
Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmíràn. (2 Kọrinti 8:8)
Àpẹẹrẹ ará Samaria rere
Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’ (Luku 10:33-35)
Ìdánwò bóyá Kristi ni Olúwa
Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. (Matiu 19:21-22)
Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀. (Marku 10:21-22)
Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. (Luku 18:22-23)
Ìwà nínú fífúnni
Ìwà Ọlọ́run
“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Johanu 3:16)
Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. (1 Johanu 4:16)
Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà. (Jakọbu 1:17)
Ìwà wa
Kí ni ìwà tí ó tọ́?
Pẹ̀lú ìfẹ́
Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi. (1 Kọrinti 13:3)
Pẹ̀lú ayọ̀
Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. (2 Kọrinti 9:7)
Báwo ni a ṣe ń fi ìfẹ́ fúnni?
Fi fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí àmì ìfẹ́ àti ìjọsìn
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi. (Eksodu 25:2)
“Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún Olúwa ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn kì yóò súnmọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn. Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa. (Eksodu 30:12-14)
Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ; (Eksodu 35:5)
...olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa, fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún aṣọ mímọ́ náà. Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa. Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá. Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi ṣittimu fún ipa kankan nínú iṣẹ́ mú un wá. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́. Àwọn olórí mú òkúta óníkìsì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn. Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose. (Eksodu 35:21-29)
...kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú oríṣìíríṣìí ọrẹ àlàáfíà rẹ wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Olúwa, ó jẹ́ tí àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà. (Lefitiku 7:14)
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdí gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe. Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpín wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. Ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ jùlọ, gbogbo ọkùnrin ni ó gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ó gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. “Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Israẹli. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́. “Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí tuntun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè. Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún Olúwa yóò jẹ́ tìrẹ. Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́. “Gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ní Israẹli jẹ́ tìrẹ. Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́. Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn-ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọ̀n ogún gera. “Ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ra àwọn àkọ́bí ọmọ màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́; wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ kí o sì sun ọ̀rá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfinásun, ẹbọ òórùn dídùn sí Olúwa. Ẹran wọn gbọdọ̀ jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí igẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì àti itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ. Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n mú wá fún Olúwa ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú Olúwa fún ìwọ àti ọmọ rẹ.” Olúwa sọ fún Aaroni pé, “O kò ní ní ogún nínú ilẹ̀ wọn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ní ní ìpín láàrín wọn; Èmi ni ìpín àti ogún rẹ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. “Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé. Láti ìsinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli, kò gbọdọ̀ súnmọ́ àgọ́ ìpàdé, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn á sì kú. Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa. Èyí ni mo wí nípa wọn. Wọn kò ní gba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.” (Numeri 18:8-24)
Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki. (1 Kronika 18:11)
Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jerusalẹmu fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Hesekiah ọba Juda. Ó sì gbéga lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn náà. (2 Kronika 32:23)
Dafidi ọba sì fi wọ́n fún Olúwa pẹ̀lú fàdákà, àti wúrà tí ó yà sí mímọ́, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ́gun. (2 Samuẹli 8:11)
“Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run, kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo. (Saamu 50:14)
Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ, (Saamu 66:13)
Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ. (Saamu 68:29)
Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù. (Saamu 76:11)
Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Israẹli yóò sìn mí; èmi yóò sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ èmi yóò béèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín. (Esekiẹli 20:40)
“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé. (Mika 4:13)
Gbogbo ohun tí a ní wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, a sì ń dá a padà fún un
“Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí. Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀. (1 Kronika 29:14-16)
Àpẹẹrẹ Ọmọdé Kristi
Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu. (Matiu 2:1)
Àpẹẹrẹ àìfi fún Olúwa
Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun, tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ. Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí. Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi, tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí. Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín. (Isaiah 43:23-24)
Fi ayọ̀ fúnni nípa títẹríba fún Olúwa/fi tinútinú fúnni
Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún oríṣìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Nísinsin yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa?” Nígbà náà àwọn aṣáájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀wàá àti alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i. Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (10,000) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin (100,000) tálẹ́ǹtì irin. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Olúwa ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni. Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi. (1 Kronika 29:5-9)
“Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí. Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀. Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsin yìí èmi ti rí i pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́. (1 Kronika 29:14-17)
Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia. Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. (2 Kọrinti 8:1-5)
Ìwà ṣe pàtàkì ju iye tí a fi fúnni lọ
“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́. Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. (Matiu 23:23)
“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe. (Luku 11:42)
...pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde. Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí. Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’ “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’ “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.” (Luku 18:10-14)
Fífúnni pẹ̀lú ìwà tí ó tọ́/Olúwa gba ẹ̀bùn náà
Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀, (Gẹnẹsisi 4:4)
Nípa ìgbàgbọ́ ní Abeli rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Kaini lọ, nípa èyí tí a jẹ́rìí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́rìí ẹ̀bùn rẹ̀, àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn. (Heberu 11:4)
Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀, mo sì tún ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. (Filipi 4:18)
Fífúnni pẹ̀lú ìwà tí kò tọ́/Olúwa kọ ẹ̀bùn náà
Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro. (Gẹnẹsisi 4:3-5)
“Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀; ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i. Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá, ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta. Kí ẹ mú ọ̀rẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun ìwúkàrà ti a sun kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá lọ fi wọ́n yangàn, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,” ni Olúwa Olódùmarè wí. “Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín, àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín, síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,” ni Olúwa wí. (Amosi 4:4-6)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá. Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá. Èmi kò ní náání wọn. Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ! (Amosi 5:22, 24)
“Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli? Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè, ibùgbé àwọn òrìṣà yín, àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ, èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe. Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,” ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára. (Amosi 5:25-27)
Èyí ni ohun mìíràn tí ẹ̀yin sì túnṣe. Ẹ̀yin fi omijé bo pẹpẹ Olúwa mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin sọkún, ẹ̀yin sì ba ara jẹ́ nítorí tì Òun kò ka ọrẹ yín sí mọ́, tàbí kí ó fi inú dídùn gba nǹkan yìí lọ́wọ́ yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti láàrín aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn sí i: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkejì rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ. (Malaki 2:13-14)
Purọ́ fún Ẹ̀mí Mímọ́
Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan. Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà? Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?” Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín. Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé. Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.” Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.” Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀. (Ìṣe àwọn Aposteli 5:1-10)
Láti dá ẹ̀ṣẹ̀ láre
“Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi. (Òwe 7:14)
Àǹfààní fífúnni
Àǹfààní fún ẹni tí ń fúnni
Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘Láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ” (Ìṣe àwọn Aposteli 20:35)
Ìbáṣepọ̀ tí ó súnmọ́ Olúwa sí i
Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú. (Matiu 6:21)
Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú. (Luku 12:34)
Ìbísí ní ọ̀run
Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. (Matiu 6:20)
Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” (Matiu 19:21)
Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́. (Luku 12:33)
“Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Olúwa. (Numeri 18:26)
Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” (Luku 18:22)
Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà, ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín. (Filipi 4:17)
Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú. (1 Timotiu 6:17-19)
Ìbísí ní ayé
Ní òpin ọdún mẹ́ta mẹ́ta, ẹ̀yin yóò mú gbogbo ìdámẹ́wàá ìre oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín. Kí àwọn Lefi (tí kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn) àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ le è bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. (Deuteronomi 14:28-29)
...àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.” (2 Kronika 31:10)
Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ, nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun. (Òwe 3:9-10)
Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní. Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura. (Òwe 11:24-25)
Fún àkàrà rẹ sórí omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà. (Oniwaasu 11:1)
Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òsùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òsùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.” (Luku 6:38)
Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé, ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé: “Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà, òdodo rẹ̀ dúró láéláé.” Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa. (2 Kọrinti 9:6-11)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu. (Filipi 4:19)
Ìpè láti dán Olúwa wò fún ìbísí ohun ìní
Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ bá à lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde fún yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì ààyè láti gbà á. (Malaki 3:10)
Ìbísí ìbùkún
Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ọrẹ yín yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ó sì fi àkọ́pò ìyẹ̀fun yín fún wọn kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yín. (Esekiẹli 44:30)
Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ. Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún. Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” (Luku 7:2-5)
Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita (èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi); obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe. Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè. Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀, nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó. (Ìṣe àwọn Aposteli 9:36-37, 40)
Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!” Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?” Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. Ó sì wí pé, ‘Korneliu, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run. (Ìṣe àwọn Aposteli 10:1-4, 31)
Iye tí a ó fi fúnni
Ìdámẹ́wàá
Ṣáájú òfin
Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.” Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo. (Gẹnẹsisi 14:20)
Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.” (Gẹnẹsisi 28:20-22)
Lábẹ́ òfin
“ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni. Mímọ́ ni fún Olúwa. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà, o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un. Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa. (Lefitiku 27:30-32)
Àìsan ìdámẹ́wàá jẹ́ jíja Ọlọ́run lólè
“Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’ “Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ. Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀-èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè. (Malaki 3:8-9)
A jẹ ìdámẹ́wàá níwájú Olúwa
Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdákan nínú mẹ́wàá nínú ìre oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apá kan. Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bu ọlá fún Olúwa Ọlọ́run yín nígbà gbogbo. Bí ibẹ̀ bá jì tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí Olúwa yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù). Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sí owó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn. Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú Olúwa níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀. (Deuteronomi 14:22-26)
A fi ìdámẹ́wàá ti àwọn ọmọ Lefi àti àwọn tálákà lẹ́yìn
“Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé. Láti ìsinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli, kò gbọdọ̀ súnmọ́ àgọ́ ìpàdé, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn á sì kú. Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa. Èyí ni mo wí nípa wọn. Wọn kò ní gba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.” (Numeri 18:21-24)
Ní òpin ọdún mẹ́ta mẹ́ta, ẹ̀yin yóò mú gbogbo ìdámẹ́wàá ìre oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín. Kí àwọn Lefi (tí kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn) àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ le è bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. (Deuteronomi 14:28-29)
Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó. (Deuteronomi 26:12)
Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin Olúwa. Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá. Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje. Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli. Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì; àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.” Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí. Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. (2 Kronika 31:4-12)
“Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́. Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí inú ilé ìṣúra. (Nehemiah 10:37-38)
Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn. Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀. (Nehemiah 13:10-11)
Àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá nínú ìdámẹ́wàá tí wọ́n gbà
“Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Olúwa. (Numeri 18:26)
Ìdámẹ́wàá nínú Májẹ̀mú Tuntun
Ọlá oyè àlùfáà Melkisedeki
Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salẹmu, àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un, ẹni tí Abrahamu sì pín ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún. Ní ọ̀nà èkínní orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “ọba òdodo”; àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú, “ọba Salẹmu,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.” Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Abrahamu baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún. Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Lefi, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Abrahamu jáde. Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Abrahamu, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí, láìsí ìjiyàn rárá ẹni kò tó ẹni tí à ń súre fún láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ju ni. Ni apá kan, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láààyè nì. Àti bí a ti lè wí, Lefi pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Abrahamu. (Heberu 7:1-2, 4-9)
Ìdámẹ́wàá sínú ilé ìṣúra
Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí. Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. (2 Kronika 31:11-12)
Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí inú ilé ìṣúra. (Nehemiah 10:38)
Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìṣúra fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìṣúra, ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, nítorí inú àwọn ará a Juda yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́. (Nehemiah 12:44)
Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. (Nehemiah 13:12)
Fífúnni ní ìwọ̀n bí Ọlọ́run ti bùkún ni
Nígbà náà ni kí ẹ ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèsè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín. (Deuteronomi 16:10)
Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni kí gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ kí ó farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ní ibi tí yóò yàn. Níbi àjọ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀sẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú Olúwa ní ọwọ́ òfo. (Deuteronomi 16:16)
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. (1 Kọrinti 16:2)
Àpẹẹrẹ fífúnni ní ìwọ̀n agbára ẹni
Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà. (Esra 2:69)
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea. (Ìṣe àwọn Aposteli 11:29)
Ẹ̀bùn tí a tẹ́wọ́gbà ni èyí tí a fi fúnni ní ìwọ̀n agbára ẹni
Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní. (2 Kọrinti 8:12)
Fífúnni pẹ̀lú ìrúbọ
Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.” (Marku 12:41-44)
Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra. Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ, nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.” (Luku 21:1-4)
Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia. Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. (2 Kọrinti 8:1-4)
Má ṣe fi ohun tí kò ná ọ ní nǹkan kan fúnni
Arauna sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá?” Dafidi sì dáhùn pé, “Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa, kí ààrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà.” Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rú ẹbọ, wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Arauna fi fún ọba, bí ọba.” Arauna sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ ó gba ọrẹ rẹ.” Ọba sì wí fún Arauna pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run mi.” Dafidi sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà. (2 Samuẹli 24:21-24)
Dafidi sì wí fún Arauna pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ìwọ ó sì fi fún mi ni iye owó rẹ̀ pípé, kí a lè dá àjàkálẹ̀-ààrùn dúró lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn.” Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Mú un fún ara rẹ, sì jẹ́ kí olúwa mi ọba kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Wò ó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.” Ṣùgbọ́n ọba Dafidi dá Arauna lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ ní pípé, nítorí èmi kì yóò èyí tí ó jẹ́ tìrẹ fún Olúwa, tàbí láti rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.” (1 Kronika 21:22-24)
Ègún nígbà tí a bá fi ohun tí a jí tàbí tí ó ní àbùkù fúnni
“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’ “Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi. “Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’ “Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn. Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn. Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí. “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí Olúwa; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. (Malaki 1:6-14)
Ọ̀nà fífúnni
“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’ “Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi. “Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’ “Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn. Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn. Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí. “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí Olúwa; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. (Malaki 1:6-14)
Àpẹẹrẹ fífúnni
Ohun àkọ́kọ́
“Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ. (Eksodu 23:10-11)
“Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i ṣe, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn. (Eksodu 34:19)
“Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.” (Eksodu 34:26)
Ẹ lè mú wọn wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ mú wọn wá sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn. (Lefitiku 2:12)
“ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. (Numeri 28:26)
Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀, mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. (Deuteronomi 26:1-2)
Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ, (Òwe 3:9)
Lójú ẹsẹ̀
“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ìre oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ. “Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi. (Eksodu 22:29)
Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. (Deuteronomi 23:21)
Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ. (Oniwaasu 5:4)
Pẹ̀lú ìṣètò ṣáájú
Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. (2 Kọrinti 9:7)
Déédéé
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. (1 Kọrinti 16:2)
Fúnra ẹni
Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo. (Eksodu 34:20)
Kí olúkúlùkù ó mú ọrẹ wá bí agbára rẹ̀ ti tó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ó fi fún un ọ̀. (Deuteronomi 16:17)
Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ-aládé ni Israẹli. (Esekiẹli 45:16)
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea. (Ìṣe àwọn Aposteli 11:29)
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. (1 Kọrinti 16:2)
Fífi pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. (1 Kọrinti 16:2)
Láìsí ìgbéraga
“Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò ni èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run. “Nítorí náà, nígbà ti ẹ́ bá ti ń fún aláìní, ẹ má ṣe fi fèrè kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní Sinagọgu àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń fi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mí mọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ. (Matiu 6:1-4)
Láti inú ọkàn
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi. (Eksodu 25:2)
Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ; (Eksodu 35:5)
...olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa, fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún aṣọ mímọ́ náà. Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa. Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá. Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi ṣittimu fún ipa kankan nínú iṣẹ́ mú un wá. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́. Àwọn olórí mú òkúta óníkìsì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn. Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose. (Eksodu 35:21-29)
Jehoaṣi sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. (2 Ọba 12:4)
Ìlànà fífúnni
Ìṣàkóso àti ìjíhìn
Láti inú àwọn ọmọ Lefi, Ahijah ni ó wà lórí ìṣúra ti ilé Ọlọ́run àti lórí ìṣúra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a yà sí mímọ́. (1 Kronika 26:20)
Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tọ̀ nípa ọba Dafidi, nípasẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti nípasẹ̀ alákòóso ọmọ-ogun mìíràn. (1 Kronika 26:26)
Kore ọmọ Imina ará Lefi olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, o ń pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ Edeni, Miniamini, Jeṣua, Ṣemaiah, Amariah àti Ṣekaniah ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré. (2 Kronika 31:14-15)
Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìṣúra fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìṣúra, ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, nítorí inú àwọn ará a Juda yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi tó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́. (Nehemiah 12:44)
Mo sì fi àlùfáà Ṣelemiah, Sadoku akọ̀wé àti ọmọ Lefi kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedaiah ṣe alákòóso àwọn yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. Mo sì yan Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah bí olùrànlọ́wọ́ ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn. (Nehemiah 13:13)
Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìyìnrere yíká gbogbo ìjọ. Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra ìtara wa. Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má ba à rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín. Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú. (2 Kọrinti 8:18-21)
Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu. (Ìṣe àwọn Aposteli 11:30)
Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu. Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ. (1 Kọrinti 16:3-4)
Àpẹẹrẹ ibi tí a kò ti béèrè ìjíhìn
Wọn kò sì bá àwọn ọkùnrin náà ṣírò, ní ọwọ́ ẹni tí wọ́n fún ní owó láti san fún àwọn òṣìṣẹ́. Torí wọ́n ṣe é pẹ̀lú òdodo tí ó pé. (2 Ọba 12:15)
Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.” (2 Ọba 22:7)
Ibi tí a ó fi fúnni
Ìdílé
Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ. (1 Timotiu 5:8)
Àwọn òbí
Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àti pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, ‘Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi,’ tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ òfin Ọlọ́run di asán nípa àṣà yín. (Matiu 15:4-6)
Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ. Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kò bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí ìyá rẹ̀ mọ́. Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.” (Marku 7:9-13)
Àwọn opó
Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkára wọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run. (1 Timotiu 5:4)
Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́. (1 Timotiu 5:16)
Àpẹẹrẹ fífúnni ní ìdílé
Èmi yóò pèsè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó ṣì ku ọdún márùn-ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má ba à di aláìní. (Gẹnẹsisi 45:11)
Josẹfu sì pèsè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn. (Gẹnẹsisi 47:12)
Àpẹẹrẹ fífúnni ní ìdílé
Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. (Lefitiku 2:3)
...kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú oríṣìíríṣìí ọrẹ àlàáfíà rẹ wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Olúwa, ó jẹ́ tí àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà. (Lefitiku 7:14)
...kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà. Ọmọ Aaroni ẹni tí ó rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀. Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Israẹli, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Aaroni àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Israẹli.’ ” (Lefitiku 7:32-34)
Mose sì sọ fún Aaroni, Eleasari àti Itamari àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù pé, “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó ṣẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, kí ẹ jẹ ẹ́ láìní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. Ẹ jẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ le jẹ igẹ̀ ẹran tí a fì níwájú Olúwa àti itan tí wọ́n gbé síwájú Olúwa, kí ẹ jẹ wọ́n ní ibi tí a kà sí mímọ́, èyí ni a ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín yín nínú ẹbọ àlàáfíà àwọn ara Israẹli. (Lefitiku 10:12-14)
Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà. Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀. Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ti òun nìkan, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ” (Numeri 5:8-10)
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdí gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe. Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpín wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. Ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ jùlọ, gbogbo ọkùnrin ni ó gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ó gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. “Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Israẹli. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́. “Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí tuntun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè. Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún Olúwa yóò jẹ́ tìrẹ. Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́. “Gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ní Israẹli jẹ́ tìrẹ. Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́. Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn-ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọ̀n ogún gera. “Ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ra àwọn àkọ́bí ọmọ màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́; wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ kí o sì sun ọ̀rá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfinásun, ẹbọ òórùn dídùn sí Olúwa. Ẹran wọn gbọdọ̀ jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí igẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì àti itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ. Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n mú wá fún Olúwa ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú Olúwa fún ìwọ àti ọmọ rẹ.” (Numeri 18:8-19)
Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà, ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ènìyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran. Gba ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín tiwọn, kí o sì fún Eleasari àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa. Lára ààbọ̀ ti Israẹli, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Lefi, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.” (Numeri 31:28-30)
Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà. Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn. (Deuteronomi 18:3-4)
Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu. (Deuteronomi 25:4)
“Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa. “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. (Nehemiah 10:35-36)
Nítorí náà ní ìgbà ayé Serubbabeli àti Nehemiah, gbogbo Israẹli ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi tókù, àwọn ọmọ Lefi náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀ fún wọn. (Nehemiah 12:47)
Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Israẹli ni yóò jẹ́ tiwọn. Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ọrẹ yín yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ó sì fi àkọ́pò ìyẹ̀fun yín fún wọn kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yín. (Esekiẹli 44:29-30)
Àwọn òṣìṣẹ́ Májẹ̀mú Tuntun
“Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín, ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un. (Matiu 10:9-10)
O sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò ìgbànú, tàbí owó lọ́wọ́. (Marku 6:8)
Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì. (Luku 9:1-3)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan méjìléláàádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà. “Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín, nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé. (Luku 10:1, 4-7)
Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni. (Galatia 6:6)
Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni. Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.” (1 Timotiu 5:17-18)
Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Senasi amòfin àti Apollo lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ohun gbogbo tí wọn nílò. (Titu 3:13)
Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò. Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ, bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run. Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. (3 Johanu 1:5-8)
A fi ẹ̀bùn ti Jesu lẹ́yìn nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ayé
Àti Joanna aya Kusa tí í ṣe ìríjú Herodu, àti Susana, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn. (Luku 8:3)
Àwọn òṣìṣẹ́ Kristẹni tí kò lo ẹ̀tọ́ wọn láti gba ìtìlẹ́yìn
Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni? Ta ni ó ṣíṣẹ́ ológun tí ó sanwó ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀? Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́ ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́ ẹran? Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì? Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi? Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè. Bí àwa ti fún irúgbìn ohun ti ẹ̀mí sínú ọkàn yín, ohun ńlá ha ni bí àwa ó ba ká ohun ti yín tí ṣe ti ara? Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù? Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má ba à ṣe ìdènà fún ìyìnrere Kristi. Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìyìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìyìnrere. Síbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo irú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ ìwé yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ògo tí mo ní láti wàásù nù. (1 Kọrinti 9:6-15)
Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìyìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. (1 Kọrinti 9:17-18)
Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́. Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni, nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. (2 Kọrinti 11:7-9)
Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá, èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn. Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín, ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi? Mo bẹ Titu, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Titu ha rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mí kan náà kọ́ ni àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ ni àwa tọ̀ bí? (2 Kọrinti 12:14-18)
A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín. (1 Tẹsalonika 2:5, 9)
Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn. Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé. (2 Tẹsalonika 3:8-9)
Àwọn òṣìṣẹ́ Kristẹni kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú èrò búburú nípa owó
Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn. Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. (1 Peteru 5:1-2)
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń gbìyànjú láti rí owó nípa ṣíṣe bí ẹni tí ó ń sin Ọlọ́run
Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. (2 Kọrinti 2:17)
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, asọ̀rọ̀ asán àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrín àwọn onílà. Ó gbọdọ̀ pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wọ́n ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ère àìṣòdodo. (Titu 1:10-11)
Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé. (2 Peteru 2:1, 3)
A gba àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níyànjú láti múra sílẹ̀
Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?” Wọ́n sì wí pé, “Rárá!” Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò-owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ọ̀kan. (Luku 22:35-36)
Ibi mímọ́/tẹ́ńpìlì
Kíkọ́ àgọ́ ìpàdé
“Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ wọn: “wúrà, fàdákà àti idẹ; aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó, ọ̀gbọ̀; irun ewúrẹ́. Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́ igbó; igi kasia; Òróró olifi fún iná títàn; òróró olóòórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóòórùn dídùn; àti òkúta óníkìsì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù efodu àti ẹ̀wù ìgbàyà. “Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn. (Eksodu 25:3-8)
Wọ́n fúnni ju bí ó ti tó lọ
Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Israẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mose fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́-ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀. Mose sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún ṣíṣe iṣẹ́ náà ju bi Olúwa ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.” Mose sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i, nítorí ohun tí wọ́n ti ní ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ. (Eksodu 36:3-7)
Kíkọ́ tẹ́ńpìlì
Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀. Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkára mi ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ti pèsè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ǹtì wúrà, ti wúrà Ofiri àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) tálẹ́ǹtì fàdákà dídára, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà. Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún oríṣìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Nísinsin yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa?” Nígbà náà àwọn aṣáájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀wàá àti alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i. Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (10,000) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin (100,000) tálẹ́ǹtì irin. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Olúwa ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni. (1 Kronika 29:2-8)
Tẹ́ńpìlì náà ná owó púpọ̀
Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀. (1 Ọba 5:17)
Títún tẹ́ńpìlì ṣe
Jehoaṣi sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún tuntun ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.” Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jehoaṣi, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Nígbà náà, ọba Jehoaṣi pe Jehoiada àlùfáà àti àwọn àlùfáà yòókù, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún títún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.” Àwọn àlùfáà fi ara mọ́ pé wọn kò nígbà owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn kò sì ní tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe mọ́ fúnra wọn. Jehoiada àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀. Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún Olúwa. Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé ọba àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò. Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé. (2 Ọba 12:4-11)
“Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó ṣírò iye owó tí a mú wá sí ilé Olúwa, tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn. Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé Olúwa. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé Olúwa ṣe. Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹmpili ṣe. (2 Ọba 22:4-6)
Ní àkókò kan, Joaṣi pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe. Ó pe àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ sì gba owó ìtọ́sí láti ọwọ́ gbogbo Israẹli láti fi tún ilé Ọlọ́run yín ṣe.” Ṣùgbọ́n àwọn ará Lefi kò ṣe é lẹ́ẹ̀kan náà. Nítorí náà ọba pa á láṣẹ fún Jehoiada olórí àlùfáà ó sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí o kò béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Lefi láti mú wá láti Juda àti Jerusalẹmu, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Israẹli fún àgọ́ ẹ̀rí?” Nísinsin yìí, àwọn ọmọkùnrin obìnrin búburú ni Ataliah ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Baali. Nípasẹ̀ ọba, wọn ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa. A ṣe ìkéde ní Juda àti Jerusalẹmu wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti béèrè lọ́wọ́ Israẹli ní aginjù. Gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn sì yọ̀, wọ́n sì mú un wá, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún. Nígbàkígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Lefi sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọba àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédé, wọ́n sì kó iye owó ńlá. Ọba àti Jehoiada fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó sì ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Olúwa. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ síwájú àti síwájú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mú un le. (2 Kronika 24:4-13)
Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa, ó sì rán Ṣafani ọmọ Asalia àti Maaseiah olórí ìlú náà, pẹ̀lú Joah, ọmọ Joahasi, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe. Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, ó sì fún un ní owó náà tí ó mú wá sí inú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Lefi ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́bodè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Manase Efraimu àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù Israẹli àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Juda àti Benjamini wọ́n sì padà sí Jerusalẹmu. Nígbà náà ni wọn sì fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń túnṣe, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé Olúwa. Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn oníṣọ̀nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Juda ti gbà láti túnṣe. (2 Kronika 34:8-11)
Títún tẹ́ńpìlì kọ́
Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà. (Esra 2:68-69)
...pẹ̀lú ipele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba. (Esra 6:4)
Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí. Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Eufurate kí iṣẹ́ náà má bà dúró. (Esra 6:8)
Títọ́jú tẹ́ńpìlì
“A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa. Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.” (Nehemiah 10:30, 39)
Ẹ̀ka mìíràn
Àwọn tí ń béèrè ẹ̀bùn
Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò. (Matiu 5:42)
Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè. (Luku 6:30)
Gbogbo ènìyàn, pàápàá àwọn onígbàgbọ́
Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àǹfààní gba, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́. (Galatia 6:10)
Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. (Romu 12:10)
Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe. (Romu 12:13)
Àwọn ọ̀tá
Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú. Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ. (Òwe 25:21-22)
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.” (Romu 12:20)
Má ṣe fún apànìyàn
Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́. (Òwe 28:17)
Fífún àwọn tálákà
Àṣẹ àti ojú ìwòye Ọlọ́run lórí fífún àwọn tálákà
A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn tálákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín. (Deuteronomi 15:11)
Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run. (Òwe 14:31)
Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá, yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe. (Òwe 19:17)
“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà? Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn? Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ, àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan. (Isaiah 58:6-10)
“ ‘Wò ó, ẹ̀ṣẹ̀ tí Sodomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ṣẹ̀ nìyìí. Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran tálákà àti aláìní lọ́wọ́. (Esekiẹli 16:49)
Ìpèsè Májẹ̀mú Láéláé fún àwọn tálákà
Òfin ìkórè àti ìpèéṣẹ́
“Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ. (Eksodu 23:10-11)
“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. (Lefitiku 19:9-10)
“ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ” (Lefitiku 23:22)
Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Nígbà tí o bá ń gun igi olifi lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. (Deuteronomi 24:19-21)
Ojúṣe aláìlópin láti pèsè ohun tí a nílò
Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà. Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò. Ẹ ṣọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún keje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbèsè ti súnmọ́,” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ tálákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe Olúwa nítorí rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ. Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. (Deuteronomi 15:7-10)
Àjọ̀dún Purimu
...gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní. (Esteri 9:22)
Ọdún Jubili
Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀. (Lefitiku 25:10)
Àpẹẹrẹ fífún àwọn tálákà
...nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un. Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀. Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba. Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀ fún amúnkùn ún. Mo ṣe baba fún tálákà; mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí. (Jobu 29:12-16)
“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì, tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ, tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀; nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba, èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá: bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ, tàbí tálákà kan láìní ìbora; bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi; bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè, ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá. Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi, àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró. (Jobu 31:16-23)
Olórí olódodo
Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya. (Saamu 72:4)
Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú. (Saamu 72:12-13)
Aya rere
Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ. O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní. (Òwe 31:10, 20)
Májẹ̀mú Tuntun
Johanu Onítẹ̀bọmi
Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” (Luku 3:10-11)
Jesu Kristi fi ara rẹ̀ hàn bí ọ̀kan pẹ̀lú àwọn tálákà
“Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì. “Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’ “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu? Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa? Tàbí tí o wà ní ìhòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́? Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò?’ “Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni.’ “Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀. Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò.’ “Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’ “Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi, ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’ (Matiu 25:31-45)
Jesu fi àpẹẹrẹ fífún àwọn tálákà hàn
Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ. Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.” Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un. Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nítorí Judasi ni ó ni àpò, ni Jesu fi wí fún un pé, ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn tálákà. (Johanu 13:27-29)
Ẹni tí ó jẹ́ alárèékérekè tẹ́lẹ̀ ń fún àwọn tálákà
Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní. (Efesu 4:28)
Àpẹẹrẹ mìíràn
Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn; Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí. (Ìṣe àwọn Aposteli 2:44-45)
Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Agabu sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Romu. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣèjọba Kilaudiu.) Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea. Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu. (Ìṣe àwọn Aposteli 11:28-30)
Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘Láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ” (Ìṣe àwọn Aposteli 20:35)
Nítorí pé ó wu àwọn tí ó wà ní Makedonia àti Akaia láti kó owó jọ fún àwọn tálákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jerusalẹmu. Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń ṣe èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbèsè fún wọn. Nítorí bí ó bá ṣe pé a fi àwọn Kèfèrí ṣe alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ. (Romu 15:26-27)
Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe. (Galatia 2:10)
Ìbùkún àti ègún
Ìbùkún fífún àwọn tálákà
Ìbùkún mímọ Olúwa
Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni Olúwa wí. (Jeremiah 22:16)
Ìbùkún ìyè
Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò. (Esekiẹli 18:7)
Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí. (Esekiẹli 18:9)
...tí kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, tí kò dá ohun ògo dúró tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ, tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò. Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó sì ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ mi. Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè! (Esekiẹli 18:16-17)
Ìbùkún lórí ìdílé
Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé: ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún. Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú, nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé; ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá. (Saamu 112:2, 9)
Ìbùkún ohun tí a nílò tí a rí
Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún. (Òwe 28:27)
Ìbùkún ìlera
Fún adarí orin. Saamu Dafidi. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní: Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́: yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀ kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀ yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀. (Saamu 41:1-3)
Ìbùkún àdúrà tí a dáhùn àti ìtọ́sọ́nà
“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà? Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn? Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ, àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan. Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ. (Isaiah 58:6-11)
Ìbùkún ìdáǹdè àti ààbò
Fún adarí orin. Saamu Dafidi. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní: Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́: yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀ kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Saamu 41:1-2)
Ìbùkún ọlá
Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú, nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé; ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá. (Saamu 112:9)
Ìbùkún lórí iṣẹ́ àti ọrọ̀
Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. (Deuteronomi 15:10)
Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. (Deuteronomi 24:19)
Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya. (Saamu 72:4)
Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú. Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀. Yóò sì pẹ́ ní ayé! A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba. Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́. (Saamu 72:12-15)
Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀; òdodo rẹ̀ sì dúró láé. (Saamu 112:3)
Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú, nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé; ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá. (Saamu 112:9)
Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá, yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe. (Òwe 19:17)
Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà. (Òwe 28:8)
Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.” (Daniẹli 4:27)
Ìbùkún èso ẹ̀mí
Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Senasi amòfin àti Apollo lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ohun gbogbo tí wọn nílò. Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jì sí iṣẹ́ rere kí wọn ba à le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso. (Titu 3:13-14)
Ìbùkún ní gbogbo gbòò
Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú. (Òwe 22:9)
Ìbùkún ayọ̀
Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní. (Òwe 14:21)
Ègún fún àwọn tí kì í fún àwọn tálákà
Ègún àdúrà tí a kò dáhùn
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú; ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́. (Òwe 21:13)
Ègún òṣì
Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn. (Òwe 22:16)
Ègún ní gbogbo gbòò
Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún. (Òwe 28:27)
Ọ̀rọ̀ mìíràn nípa fífún àwọn tálákà
Ìwà àánú
Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí? (Jobu 30:25)
Ṣe ìwádìí ohun tí àwọn tálákà nílò
Mo ṣe baba fún tálákà; mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí. (Jobu 29:16)
A fi ẹ̀sùn kan olùfọkànsìn pé kò fún àwọn tálákà
Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye? Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa. Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo, apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́. (Jobu 22:5, 7, 9)
Àpẹẹrẹ fífi ògo fún Ọlọ́run dípò fífún àwọn tálákà
Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀. Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí? Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.” Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi. Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrín yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo. Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìnrere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.” (Matiu 26:6-13)
Nígbà tí ó sì wà ní Betani ni ilé Simoni adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti alabasita òróró ìkunra olówó iyebíye, ó ṣí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jesu lórí. Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò? Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi? Nígbà gbogbo ni àwọn tálákà wà ní àárín yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkígbà tí ẹ bá fẹ́. (Marku 14:3-7)
Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òsùwọ̀n lita kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́. Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.” (Johanu 12:3-8)
Títọ́jú àwọn opó jẹ́ dandan
Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́. Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí. (Ìṣe àwọn Aposteli 6:1-3)
Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti Baba ni èyí, láti máa bojútó àwọn aláìní baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láìlábàwọ́n kúrò nínú ayé. (Jakọbu 1:27)
Àbájáde ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa níní nǹkan: kò sí tálákà
Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan. Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn. (Ìṣe àwọn Aposteli 4:32-33)
Ìpèsè wà kí àwọn tálákà lè fúnni ní díẹ̀
“ ‘Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun. “ ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá, kí ó mú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. (Lefitiku 5:7, 11)
“ ‘Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá kọjá kí ó mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá fún àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ẹbọ sísun àti ọmọ ẹyẹlé tàbí àdàbà kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Bí kò bá lágbára àti fi àgùntàn ṣe é, ó gbọdọ̀ le mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un. Òun yóò sì di mímọ́.’ ” (Lefitiku 12:6, 8)
“Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òsùwọ̀n lógù òróró àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. (Lefitiku 14:21-22)
Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ. Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.” Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀. (Lefitiku 14:30-32)
Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ dé bi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá síwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́. (Lefitiku 27:8)
Àwọn òbí Jesu wà nínú ẹgbẹ́ yìí
Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa (bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”), àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.” (Luku 2:22-24)
Nígbà ìkànìyàn, ọlọ́rọ̀ àti tálákà fi iye kan náà fúnni
“Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún Olúwa ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn kì yóò súnmọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn. Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa. Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì ṣékélì lọ, àwọn tálákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì ṣékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín. (Eksodu 30:12-15)
Fífún àwọn tálákà lè jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà
Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!” Jesu sì wí fún un pé, “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu. (Luku 19:8-9)
Àpẹẹrẹ mìíràn ti fífúnni (kì í ṣe fún Olúwa)
Lẹ́yìn tí àwọn ìbákasẹ náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọ̀n ṣékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n ṣékélì wúrà mẹ́wàá. Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rebeka, ó fún arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú. (Gẹnẹsisi 24:22, 53)
Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀. Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Benjamini, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Josẹfu. (Gẹnẹsisi 43:11-12, 15)
Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.” Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni. (2 Kronika 9:8-9)
Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀. (2 Kronika 9:12)
Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́. (2 Kronika 30:24)
Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jerusalẹmu fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Hesekiah ọba Juda. Ó sì gbéga lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn náà. (2 Kronika 32:23)
Josiah sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ jẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọmọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọ màlúù, gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba. Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Hilkiah, Sekariah àti Jehieli, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹran ọ̀sìn. Àti pẹ̀lú Konaniah àti pẹ̀lú Ṣemaiah àti Netaneli, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabiah, Jeieli àti Josabadi olórí àwọn ọmọ Lefi, ó sì pèsè ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ẹbọ ìrékọjá àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Lefi. (2 Kronika 35:7-9)
Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ” Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá. (Esra 1:4, 6)
Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá (2,200) mina fàdákà. Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) mina fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. (Nehemiah 7:70-72)
Ọba sì ṣe àsè ńlá, àsè Esteri, fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì kéde ìsinmi jákèjádò ìgbèríko ó sì pín ẹ̀bùn fún wọn pẹ̀lú bí ọba ṣe lawọ́ tó. (Esteri 2:18)
Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù wọn yóò mú ọrẹ wá fún un; àwọn ọba Ṣeba àti Seba wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un. (Saamu 72:10)
Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremiah pẹ̀yìndà láti máa lọ, Nebusaradani fi kún un wí pé, “Padà tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu lọ, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ìlú Juda, kí o sì máa gbé ní àárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ.” Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ. (Jeremiah 40:5)
Láti tu àwọn ẹlòmíràn lójú
Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún Esau arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀. Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún un pé, ‘Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jakọbu ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Esau lójú pé bóyá inú Esau yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé. (Gẹnẹsisi 32:13, 20)
Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?” Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.” Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.” Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi. Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á. (Gẹnẹsisi 33:8-11)
Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò: àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá, dẹ́kun ìbínú líle. (Òwe 21:14)
Láti nípa lórí àwọn ẹlòmíràn
Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà. Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san án, kí ẹ sá à jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.” (Gẹnẹsisi 34:11-12)
Láti wá ọgbọ́n
Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀. Ní ọdọọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹṣin àti ìbáaka wá. (2 Kronika 9:23-24)
Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà, tùràrí olóòórùn dídùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dàbí irú èyí tí ayaba Ṣeba fi fún Solomoni ọba. (1 Ọba 10:10)
Àwọn ènìyàn búburú ń ṣe àjọyọ̀ ikú olùfọkànsìn
Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró. (Ìfihàn 11:10)
Ọ̀rọ̀ mìíràn nípa fífúnni
Ibi tí a ó ti fúnni
“Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀. (Eksodu 23:19)
“Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.” (Eksodu 34:26)
Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín. (Deuteronomi 12:6)
Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa. (Deuteronomi 12:11)
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àkọ́bí àwọn màlúù yín, tàbí ti ewúrẹ́ ẹ yín, ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ àtinúwá, tàbí ẹ̀bùn pàtàkì ní ìlú ẹ̀yin tìkára yín. Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àwọn ọmọ Lefi láti ìlú u yín, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín. (Deuteronomi 12:17-18)
A lè má ní owó láti fúnni, ṣùgbọ́n a lè fi Kristi fúnni
Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ. Nígbà tí ó rí Peteru àti Johanu bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹmpili, ó ṣagbe. Peteru sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Johanu, ó ní “Wò wá!” Ó sì fiyèsí wọn, ó ń retí láti rí nǹkan láti gbà lọ́wọ́ wọn. Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.” (Ìṣe àwọn Aposteli 3:2-6)
Ọ̀làwọ́ yóò rí ọ̀pọ̀ ìbéèrè
Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí; gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́. (Òwe 19:6)
Ojúkòkòrò lè ṣàkóbá fún fífúnni
Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe. (2 Kọrinti 9:5)
Fífúnni ń mú ìdúpẹ́ wá fún Ọlọ́run
Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. (2 Kọrinti 9:12)
Má ṣe fúnni kí o tó gbìyànjú láti làjà
“Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀. (Matiu 5:23-24)
Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú láti fúnni
Wò ó, lórí àwọn òkè, àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá, ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà. Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́, kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́; wọn yóò sì parun pátápátá. (Nahumu 1:15)
Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ. (Heberu 13:16)
Fífúnni lè jẹ́ ẹ̀rí
Jesu sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnìkan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mose pàṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.” (Matiu 8:4)
Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.” (Marku 1:44)
Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.” (Luku 5:14)
Àpẹẹrẹ fífún orílẹ̀-èdè kan
“Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún púpọ̀, mo wá sí Jerusalẹmu láti mu ẹ̀bùn wá fún àwọn ènìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀. (Ìṣe àwọn Aposteli 24:17)
Ohun tí ó dára ju ẹbọ lọ
Ìfẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò
Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.” (Marku 12:33)
Ìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run àti mímọ̀ ọ́n
Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ. (Hosea 6:6)
Ìgbọràn
Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ. (1 Samuẹli 15:22)
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí. “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ. (Isaiah 1:11)
Òdodo/ìdájọ́ òdodo
Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ. (Òwe 21:3)
Ọrẹ
Ti dandan
“ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan. Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un. Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà. “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀. Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí. Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo. (Esekiẹli 46:11-15)
Ti àtinúwá
Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un. Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà. (Esekiẹli 46:12)
Àpẹẹrẹ ọrẹ
Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Israẹli rú ẹbọ níwájú Olúwa. Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárín tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà. (1 Ọba 8:62-64)
“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ” Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá. (Esra 1:2, 4, 6)
Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu, pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Babeli àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹmpili Ọlọ́run wọn ní Jerusalẹmu. Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rú ẹbọ lórí pẹpẹ tẹmpili Ọlọ́run rẹ ní Jerusalẹmu. Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tókù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín. Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹmpili Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba. Èmi, ọba Artasasta, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Eufurate láìrójú láti pèsè ohunkóhun tí àlùfáà Esra, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín tó ọgọ́rùn-ún kan tálẹ́ǹtì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òsùwọ̀n àlìkámà, àti dé ọgọ́rùn-ún bati ọtí wáìnì, àti dé ọgọ́rùn-ún bati òróró olifi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀. (Esra 7:15-18, 20-22)
Bí ẹ̀bùn ẹ̀mí rẹ bá jẹ́ fífúnni, lò ó
Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é. (Romu 12:6-8)
Fúnni láti pèsè ohun tí a nílò
Nígbà tí wọ́n fi òsùwọ̀n omeri wọ̀n-ọ́n, ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un. (Eksodu 16:18)
Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba. Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín, kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.” (2 Kọrinti 8:13-15)